IROYIN NIPA ILE ISE IRANSE YI
(News About this Ministry)
A fi gbogbo ogo fun Olorun alaaye fun ohun iyanu nla ti o ngbe se nipase Ise Iranse yi. Nitoripe, opolopo awon omo Olorun lo njeri si ohun nla ati iyanu ti Oluwa ti se ninu aiye won nipase Ise Iranse ipago “Mofebo ati Wakati Iyanu Temi”, ati Adura ori aago ero ibanisoro “Wakati Iyanu” ojoojo Isegun (every Tuesday).
Nitorina, pelu igbagbo ninu Olorun kan yi, mo so tele sinu aiye yin nipataki iwo ti o nka oro yi wipe; iwo ni iroyin ati eri iyanu kan ni Oruko Jesu!
Bakanna, nipase Ise Iranse yi, akainiye eniyan lo ti ri iyanu lori ise ati idile won. Opolopo ti gba Iwosan kuro ninu aisan olojo pipe. Opolopo ti aiye ati Dokita ti so wipe ko le bimo lo ti di olomo laye. Leekan sii, a fi gbogbo ogo fun Oluwa! Igbagbo wa si'nbe nipe Olorun wa ti o se eleyi ko ti yipada, nitorina iwo ni eri kan laipe!
Awon ona meji ti a fi se le je alabapin ninu ise iranse ti gbogbo ojo isegun (Tuesday) yi ni:
Ona kinni: Ki a te nomba yi ni ori ero ibanisoro wa (1712-432-3100/498243).
Ona Keji: Tabi ki a darapo pelu awon omo Olorun ninu ipago wa ti olosu merin-merin ti o maa nwaye ni Ilu Atlanta ni Jimoh Keta ninu Osu Keji, Osu Keje, ati Osu Kokanla, Odun (Third Friday of February; July; and November).