NJE IWO MO JESU KRISTI?
Mo fe ki e mo lonu wipe, Olorun feran re!
Bibeli so wipe, ‘ Nitori Olorun fe araiye tobee ge ti o fi Omo bibi re kansoso funni, ki enikeni ti o ba gba a gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun”
Isoro ibe ni wipe: Gbogbo wa ni o ti se, tabi, se ohun ti o lodi. Eyi ni a npe ni ese, ese wa si ti yawa nipa kuro lodo Olorun.
Bibeli so wipe “Gbogbo enia li o sa ti se, ti won si ti kuna ogo Olorun”. Olorun pe, o si je mimo, ati wipe ese wa ya wa kuro lodo Olorun titi lai. Bibeli so wipe “iku ni ere ese.”
Irohin rere ni wipe, ni nkan bi egberun odun meji sehin, Olorun ran Omo Re nikan soso lati ku fun ese wa.
Jesu ni Omo Olorun. O gbe igbe aye alailese o si ku lori agbelebu lati san gbese fun ese wa. “ Olorun fi ife han si wa paapa nigbati awa je elese; Kristi ku fun wa.”
Jesu ji dide kuro ninu oku osi ngbe orun pelu Olorun Baba Re. O fi ebun iye aiyeraye han funwa—ati pelu wipe ki a le gbe papo pelu Re ni Orun bi a ba lee gbaa gbo gegebi Oluwa ati Olugbala wa. Jesu wi fun wa pe “Emi li ona, ati otito, ati iye: ko si enikeni ti o le wa sodo Baba, bikose nipase mi.”
Olorun na owo ife si o, O si nfe ki o je omo Re. “ Sugbon iye awon ti o gbaa, awon li aa fi agbara fun lati di Omo Olorun, ani awon naa ti o gba oruko re gbo.” Iwo naa le yan lati bere idariji lowo jesu Kristi fun idariji ese re, ki o si wo inu aye re lo gegebi Oluwa ati Olugbala re.
Bi o ba fe gba Kristi o lee so Fu un ki O je Olugbala ati Oluwa bi oo ti gba adura yi…
”Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe omo Olorun ni iwo nse. Mo dupe fun iku re lori agbelebu tori awon ese mi. Jowo dari awon ese mi ji mi ki o si fun mi ni iye ainipekun. Mo gba adura wipe ki o wo inu aye mi ati okan mi gegebi Oluwa ati olugbala mi. Mo fe maa sin o ni gbogbo igba.”
Nje o gba adura yi?
Fun Adura t'abi iranlowo nipa igbese yi, o le pe wa lori ero ibanisoro wa 404-597-1270 (USA).